Àjàkáyé-àrùn èrànkòrónà ọdún 2019-2020
From Wikipedia, the free encyclopedia
Àjàkáyé-àrùn èrànkòrónà ọdún 2019-2020 tàbí Àjàkáyé-àrùn COVID-19 ni àjàkáyé-àrùn tí ó ṣẹlẹ̀ ní ààrin ọdún 2019 àti 2020 tí ò ń tàn káàkiri orílẹ̀ èdè gbogbo àgbáyé lọ́wọ́lọ́wọ́. Kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn kòrónà tí ó ń ṣàkóbá fún èémí ọ̀wọ́ kejì (SARS-CoV-2) ló ṣokùnfà àjàkálẹ̀ àrùn náà. Àgbègbè Wuhan, ní ìlú Hubei, lórílẹ̀-èdè China ní àjàkálẹ̀ àrùn yìí tí kọ́kọ́ farahàn lóṣù Kejìlá ọdún 2019, tí ó sìn ti di nǹkan tí àjọ tí ó ń rí sì ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization tí kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àrùn pàjáwìrì gbogboògbò lágbàáyé tí wọ́n gbọdọ̀ mójú tó. Titi di ọjọ́ kẹwàá oṣù ó ti ọdún 2020, ó ti ju ènìyàn 118,000 tí ó ti kó àrùn yìí káàkiri gbogbo àgbáyé, tí 5,800 nínú wọn jẹ èyí tí wọ́n kà sí pé àrùn náà tí wọ̀ wọ́n lára jù.[1] Ó ti ju orílẹ̀-èdè àádọ́fà (115) tó ti kàgbákó ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀ràn kòrónà lọ́dún yìí, pàápàá jùlọ àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè China, Italy, South Korea àti Iran. Ó ti ju ènìyàn ìgbàlélẹ́gbẹ̀rúnmẹ́rin, 4,200 tí àrùn yìí ti pa ní ìfọnnáfòṣu, ó tó ènìyàn ọgọ́rùn-ún-lé-lẹ́gbẹ̀ta, (3100) tí wọ́n kú ní orílẹ̀ èdè China nìkan, àti ẹgbẹ̀rún kan ènìyàn káàkiri àwọn orílẹ̀ èdè op kù káàkiri àgbáyé. Bẹ́ẹ̀ náà, ó ti ju ènìyàn mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ẹgbẹ̀rún (64,000) tí wọ́n ti mórí bọ́ nínú àjàkálẹ̀ àrùn yìí. Ẹ̀rà yìí máa ń ràn láti ara enikan sí ẹlòmíràn nípa èémí ìpọ̀jáde bí a bá ń wúkọ̀ tàbí bí a bá ń sín.[2]
Àkókò tí ènìyàn bá kó àrùn yìí àti ìgbà tí ó máa farahàn ma ń sábà máa ń tó Ọjọ́ márùn-ún, ṣùgbọ́n nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó lè tó nǹkan bí ọjọ́ méjì sí mẹ́rìnlá.[3] Àwọn àmìn ìfarahàn rẹ̀ sáà a máa ń wá bí, àìsàn ibà, ikọ́ wúwú, àti àìlèmí kánlẹ̀. Ìpeléke àrùn yìí máa ń fà àrùn ẹ̀dọ̀fóró, àti ìnira èémí. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àrùn yìí kò gbóògùn kankan. Ṣùgbọ́n ìwádìí ìjìnlẹ̀ ń lọ lórí rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìgbìyànjú láti mójú tó àwọn àmìn ìfarahàn rẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ìwòsàn ń ṣe. Àwọn ọ̀nà tí wọ́n là kalẹ̀ láti dẹ́kun àrùn yìí fífọwọ́ déédé, jíjìnnà sí ara ẹni, pàápàá jùlọ ẹni tí ó bá ń ṣàìsàn tàbí fura sí pé wọ́n ní àrùn yìí àti ìyaraẹnisọ́tọ̀ ẹni tí ó fura pé òun ní àrùn yìí.[4]
Lára àwọn ọ̀nà ìdẹ́kun mìíràn tí wọ́n ń gbà láti dẹ́kun jíjàkálẹ̀ àrùn yìí káàkiri àgbáyé ni dídẹ́kun ìrìn-àjò, ìyà sọ́tọ̀ ẹni-afurasí, òfin kónílé-ó-gbélé, àti títi àwọn ilé-ìwé pa. Àwọn ìlú bíi Hubei lórílẹ̀ èdè China àti gbogbo orílẹ̀ èdè Italy ló wà ní ìyàsọ́tọ̀-àmójútó lọ́wọ́ báyìí, bẹ́ẹ̀ náà òfin kónílé-ó-gbélé ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀ èdè China àti South Korea; bẹ́ẹ̀ náà, àyẹ̀wò fínnífínní ní pápákọ̀-òfuurufú àti ìdíkọ̀ ọkọ̀ ojúrìn;àti ìmọ̀ràn ìrìn-àjò ní ìlú tàbí àgbègbè tí àrùn yìí bá ti ń jàkálẹ̀. Ilé-ìwé títìpa pátápátá ní gbogbo orílẹ̀-èdè tàbí àgbègbè tí àrùn yìí ti ṣẹ́yọ ní àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, èyí tí ṣe àkóbá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀ọ́dúnrún mílíọ́nù (300 million) àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jákèjádò àgbáyé.[5] Àkóbá ńlá mìíràn tí Ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀ràn kòrónà lọ́dún 2019-20 yìí ni ìfàsẹ́yìn ètò ọ̀rọ̀-aje àti ìbágbépọ̀,[6][7] bẹ́ẹ̀ náà Ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀ràn kòrónà lọ́dún 2019-20 ti fa ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ìjà-aòfẹ́-ọ-nílùú wá sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China àti àwọn ọmọ ìran ìlà oòrùn Asia, bákan náà ìròyìn òfegè lórí ìkànnì ayélujára nípa Ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀ràn kòrónà lọ́dún 2019-20 àti àwọn aríjẹ-nídìí ìbàjé lórí àjàkálẹ̀ àrùn náà kò gbẹ́yìn.[8][9]