Àjọ Ìlera Àgbáyé
Àjọ tí ó ń rí sí ìlera ara káàkiri àgbáyé / From Wikipedia, the free encyclopedia
Àjọ Ìlera Àgbáyé ti agekuru re nje WHO jẹ́ àjọ Àgbájọ àwọn Orílẹ̀-èdè Aṣòkan tí wọ́n dá sílẹ̀ fún ètò ìlera gbogbo àgbáyé[1]. Erongba dida WHO sile ni "ki gbogbo eniyan le de ipele ilera to ga ju to see see".[2] Olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ wà ní Geneva, Swítsàlandì,[3] o si ni ile-ise agbegbe mefa ati ibi ise àádọ́jọ kaakiri agbaye.
Àjọ Ìlera Àgbáyé | |
---|---|
Àsíá Àjọ Ìlera Àgbáyé | |
Irú | ẹ̀ka Àjọ àwọn Orílẹ̀-èdè |
Orúkọkúkúrú | WHO OMS |
Olórí | Margaret Chan, Alákóso |
Ipò | Active |
Dídásílẹ̀ | Oṣù Kẹrin 7, 1948; ọdún 76 sẹ́yìn (1948-04-07) |
Ibùjókòó | Geneva, Swítsàlandì |
Ibiìtakùn | who.int |
Òbí | United Nations Economic and Social Council (ECOSOC) |
Wọ́n dáa WHO sílẹ̀ ní Ọjọ́ keje Oṣù kẹrin Ọdún 1948.[4][5] Ipade akoko ti apejo ilera agbaye, ajo ti o n sakoso WHO, waye ni ojo kerinlelogun osu keje odun naa. Àjọ Ìlera Àgbáyé gba awon dukia, osise, ati ojuse Ajo Ilera ti Ajumose Orilede, ile-ise agbaye d'Hygiène Publique, ati isori ailera gbogboogbo mora.[6] Ise re bere ni odun 1951 leyin asopo ti oro inawo ati ise ona to lapere.[7]
Ète àti èròngbà aájọ WHO ni láti mú kí ìlera pé káàkiri àgbáyé. Wọ́n ma ń ran àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé lọ́wọ́ láti kọjú àrùn, wọ́n sì ma ń ṣe òfin nípa ètò ìlera láti mú kí ìlera péye.
Àjọ WHO kó ipa ribiribi nínú líle àrùn smallpox sígbó, nínú ìṣẹ́gun ribiribi tí ìran ènìyàn ti ní lórí Àrùn Polio, àti nínú ṣíṣe abẹ́rẹ́ ajé sára Àrùn Ebola. Àwọn nkan tí ó múmú láyà wọn lọ́wọ́ ni ọ̀nà láti ségun àwọn àrùn tí ó sé ràn, pàápàá jù lọ àrùn HIV/AIDS, Ebola, COVID-19, malaria àti tuberculosis; àwọn àrùn tí ó sé ràn bi àrùn ọkàn àti cancer; àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.