Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì
ogun tó ṣẹlẹ̀ láàrin ọdún 1939 àti 1945 láàgbáyé / From Wikipedia, the free encyclopedia
Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì tàbí Ogun Agbáyé Kejì jẹ́ ogun tí ó pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè agbáyé pọ̀ lẹ́ẹ̀kan-ṣoṣo tí ó bẹ̀ ní àárín ọdún 1939 sí ọdún 1945. Ogun yí jẹ́ èyí tí ó kan gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè agbáyé tí wọ́n jẹ́ alágbára tí wọ́n sì lààmì-laaka. Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jagun náà ni a lè pin sí méjì. Àwọn apá kíní ni Òngbèjà nígbà tí àwọn apá kejì jẹ́ Atọ́jà. Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ jagun-jagun tí wọ́n kópa nínú ogun yí jẹ́ ọgbàọ́rùn un mílíọ́nù láti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n lápapọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ oníjà gan an sa ipá wọn nípa lílo gbogbo ọrọ̀-ajé, ìṣúná, ilé-iṣẹ́ jànkàn-jànkàn, ìwádí ìmọ̀ sáyéẹ́nsì tí wọ́n ní láti fi jagun náà, èyí kò jẹ́ kí á mọ̀ nkan ogun àwoọ́n ọmọ ogun nikan ni àwọn orílẹ̀-èdè yí ló láti fi jagun ni tàbí wọ́n lo àwọn nkan mìíràn tí kìí ṣe ti Olohun tí ó jẹ́ ti àwọn ará ìlú lásán. Ogun agbáyé ẹlẹ́kejì yí jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn ogun tí èmi ati dúkìá ti ṣòfò jùlo lágbàáyé nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ọmọ adáríhurun. Àwọn ológun tí wọ́n sọ ẹ̀mí wọn nu níbi ìjà-àgbà yí jẹ́ mílíọ́nù ọ́nà àádọ́rin àti mílíọ́nù lọ́nà márùndínláàdọ́taọ́sàn án ènìyàn, nígbà tí àwọn tí wọ́n kú jùlọ jẹ́ ará ìlú lásán tí wọn kìí ṣe jagun-jagun. Ohun tí ó fàá tí òkú yí fi pọ̀ tó bẹ̀ẹ́ ni ìwà ìmọ̀ọ́mọ̀-ṣekú pa ọ̀pọ̀ ènìyàn tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pe ní jẹ́nósáìtì, nípa ìlànà ìfebipani , pípa àwọn aláìṣẹ̀ àti fífi ajàkálẹ̀ àrùn pani. Wọ́n ṣamúlò àwọn bàlúù dìgbòlùjà nínú ogun àgbáyé yí, ba kan náà ni wọ́n tún lo àwọn àdó olóró tí ó le pa ìlú run, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n tun lo nuclear weaponsláti jagun lásìkò náà., lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ iwe àdéhùn ati òfin oríṣiríṣi
Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì | |||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|
Clockwise from top left: Chinese forces in the Battle of Wanjialing, Australian 25-pounder guns during the First Battle of El Alamein, German Stuka dive bombers on the Eastern Front winter 1943–1944, US naval force in the Lingayen Gulf, Wilhelm Keitel signing the German Surrender, Soviet troops in the Battle of Stalingrad | |||||||
| |||||||
Àwọn agbógun tira wọn | |||||||
Àwọn Alájọṣepọ̀ Ìsọ̀kan Sófìẹ̀tì (1941–45)[nb 1] France[nb 2] |
Àwọn Olóòpó Germany Hungary (1941–45) Co-belligerents Puppet states | ||||||
Àwọn apàṣẹ | |||||||
Allied leaders Joseph Stalin |
Axis leaders Adolf Hitler | ||||||
Òfò àti ìfarapa | |||||||
Military dead: Over 16,000,000 Civilian dead: Over 45,000,000 Total dead: Over 61,000,000 (1937–45) ...further details |
Military dead: Over 8,000,000 Civilian dead: Over 4,000,000 Total dead: Over 12,000,000 (1937–45) ...further details |