W. E. B. Du Bois
From Wikipedia, the free encyclopedia
William Edward Burghardt Du Bois (pípè /duːˈbɔɪs/ doo-BOYSS;[1] Osu Keji 23, 1868 – Osu Kejo 27, 1963) je ara Amerika to je alakitiyan awon eto araalu, Pan-Afrikanisti, onimo oro-awujo, olukowe itan, oludako, ati olootu. David Levering Lewis to je olukowe itan koole pe, "Nigba ajo ise re fun ojo pipe, W. E. B. Du Bois gbiyanju gbogbo ojutu to se e se si isoro iseleyameya orundun ogun —igbowo eko, propaganda, ilopo, ipinu funraeni tomoorile-ede, awon eto omoniyan, isepinya asa ati okowo, iselu, isekomunisti kariaye, ikoreyinodi, itileyin orile-ede agbaye keta."[2]
W. E. B. Du Bois | |
---|---|
W. E. B. Du Bois in 1918 | |
Ìbí | William Edward Burghardt Du Bois (1868-02-23)Oṣù Kejì 23, 1868 Great Barrington, Massachusetts, U.S. |
Aláìsí | August 27, 1963(1963-08-27) (ọmọ ọdún 95) Accra, Ghana |
Pápá | Civil rights, sociology, history |
Ilé-ẹ̀kọ́ | Atlanta University, NAACP |
Ibi ẹ̀kọ́ |
|
Doctoral advisor | Albert Bushnell Hart |
Ó gbajúmọ̀ fún |
|
Influences | Alexander Crummell William James |
Àwọn ẹ̀bùn àyẹ́sí | Spingarn Medal 1920 Lenin Peace Prize 1959 |
Signature |
Du Bois pari eko re ni Harvard, nibi to ti gba iwe-eri omowe (Ph.D) ninu Itan; leyin re o di ojogbon itan ati oro-okowo ni Atlanta University. O di olori Egbe Omoorile-ede fun Iresiwaju awon Eniyan Alawo (NAACP) ni 1910, o si di oludasile ati olootu iwe-olosoosu NAACP The Crisis. Du Bois bo si akiyesi tomoorile-ede nigba to tako ero Booker T. Washington lati faramo ipinya Jim Crow larin awon alawofunfun ati alawodudu ati igbaetokuro lowo awon alawodudu igbana, o sakitiyan dipo re fun iposi isoju oloselu fun awon alawodudu lati le ba semudaju awon eto arailu, ati idasile elite awon Alawodudu ti won yio sise fun ilosiwaju eya awon omo Afrika Amerika.[3]