Nils Olav
Penguin tí ó ń gbé ní Edinburgh Zoo, Scotland / From Wikipedia, the free encyclopedia
Colonel-in-Chief Sir Nils Olav jẹ́ ọba Penguin tí ó ń gbé ní Edinburgh Zoo, Scotland. Ó jẹ́ ẹran ọ̀sìn fún ológun tí wọ́n máa ń lò nígbà ayẹyẹ tàbí gẹ́gẹ́ bí ààmi àpẹẹrẹ[1][2][3] , tí ó sì jẹ́ Ọ̀gágún Colonel fun Royal Guard ti orílẹ̀ èdè Norway. Àwọn ológun lati Norwegian Royal Guard bẹ Nils wò ní Ọjọ́ karùndílógún Oṣù kẹjọ Ọdún 2008 tí wọ́n sí fi oyè Knighthood dáa lọ́lá.[4] King Harald V ni ó pàṣé wípé kí wọ́n fi oyè yìí dáa lọ́lá. Nígbà ayẹyẹ yìí, ènìyàn ọgọrún meje ló darapọ̀ mọ́ àwọn aṣọ́gbà ẹranko 130 lati gbọ́ gbólóhun tí ọba kà jade tí ó ṣàpèjúwe Nils gẹ́gẹ́ bíi penguin "tí ó pójúùwọ̀n ní gbogbo ọnà lati gba ọlá àti iyì knighthood".[5] Orúkọ 'Nils Olav' yìí ní wọ̣́n tún fún àwọn king penguins méjì tí ó wà lẹ́yin Nils Olav lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí gẹ́gẹ́ bíi Ọba Aṣọ́gbà másíkọ́ọ̀tí.[6]
Sir Nils Olav | |
---|---|
Sir Nils Olav | |
Born | Edinburgh Zoo, Scotland |
Service/branch | Norwegian Army |
Years of service | 1972–1987 (àkọ́kọ́), 1987–current (ẹ̀kejì) |
Rank | Colonel-in-Chief & mascot |
Unit | Hans Majestet Kongens Garde |