Juliette Binoche
From Wikipedia, the free encyclopedia
Juliette Binoche (ìpè Faransé: [ʒyljɛt binɔʃ]; tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹ́ta, ọdún 1964) jẹ́ Òṣèrè àti Oníjó Faransé. Ó ṣe àfihàn ní fíìmù bíi ọgọ́ta tí wọ́n pè é sí àti wí pé ó tún jẹ́ ẹni tó gba àwọn àwọ́ọ̀dù bíi Àwọ́ọ̀dù Akadẹ́mì, British Academy Film Award, Silver Bear, Cannes Film Festival Award, Volpi Cup àti César .
Juliette Binoche | |
---|---|
Binoche at the 72nd Berlin International Film Festival, 2022 | |
Ọjọ́ìbí | 9 Oṣù Kẹta 1964 (1964-03-09) (ọmọ ọdún 60) Paris, France |
Orúkọ míràn | "La Binoche" |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Conservatoire National Supérieur d'Art Dramatique |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1983–present |
Alábàálòpọ̀ |
|
Àwọn ọmọ | 2 |
Awards | Full list |
Website | juliettebinoche.net |
Signature | |
Binoche bẹ̀rẹ sí ní má kọ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe eré ní ọ̀dọ́ . Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tó ṣe lórí ìtàgé, orúkọ rẹ̀ wa nínu fíìmù tí gbogbo ènìyàn mọ̀ síauteur tí Jean-Luc Godard jẹ́ atọ́kùn rẹ̀ (Hail Mary, 1985), Jacques Doillon (Family Life, 1985), ati André Téchiné; tí eré ìgbẹ̀yìn yìí jẹ́ kó di gbajúgbajà ní Faransé tí ó fi jẹ́ kí ó di olórí Òṣèrè ní eré oníṣe Rendez-vous (1985). Eré àkọ́kọ́ tó jẹ́ ti Gẹ̀ẹ́sì tó ṣe The Unbearable Lightness of Being (1988), tí eré yìí jẹ́ kó di ènìyàn tí àwọn ènìyàn púpọ̀ wá mọ̀. Lẹ́yìn náà eré tó kópa Krzysztof Kieślowski tí orúko eré náà ń jẹ́ Three Colours: Blue (1993).
Nígbà ọdún 2000, Ó ti wà nípò ẹni tó ti ṣe àṣeyọrí tí kò dẹ̀ fẹ́ kó bọ. Bí ó ṣe ń ṣe eré Gẹ̀ẹ́sì náà lọ ń ṣe ti Faransé. Ní ọdún 2010, Ó gba àwọ́ọ̀dù fún Òṣèrè tó dára jùlọ lóbìnrin ní Cannes Film Festival fún ipa rẹ́ gẹ́gẹ́ bí Abbas Kiarostami ní eré tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Certified Copy. Wọ́n tún fún ní àwọ́ọ̀dù Maureen O'Hara Award ní Kerry Film Festival ní ọdún 2010, àwọ́ọ̀dù tó jẹ́ wí pé obìnrin tó bá ṣe àṣeyọrí ní isẹ́ Òṣèrè nìkan ló má fún .[1]