Journalism
From Wikipedia, the free encyclopedia
Iṣẹ́ ìròyìn jẹ́ kíkọ àti pínpínká àwọn àpilẹ̀kọ bíi : ìtàkurọ̀sọ, ìṣẹ̀lẹ̀, òkodoro-ọ̀rọ̀, ìròrí àti àpilẹ̀kọ nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹyọ nínú ìròyìn ojoojúmọ́ láti fi ṣe ìfitónilétí fún àwọn ènìyàn àwùjlóòrèkóòrè. Gbólóhùn ìròyìn jẹ́ ohun tí a lè fi sọrí àwọn tí wọ́n ń kó ohun tí a mọ̀ sí ojúlówó ìròyìn jọ kí etí àwọn ènìyàn àwùjọ ó má ba gbófo, òníọ̀hún jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Iṣẹ́ oníròyìn yàtọ síra wọn ní ìlú ati orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, iṣẹ́ ìròyìn àti àwọn oníròyìn kò dá dúró nítorí wípé ìjọba ni ó ń ṣakóso rẹ̀. [1] l. Bá kan náà ni iṣẹ́ ìròyìn ati àwọn oníròyìn náà ń da ṣíṣẹ́ tí wọn kò sì sí lábẹ́ àkóso ìjọba ní orílẹ̀-èdè míràn. Bẹ́ẹ̀ sì ni orísiríṣi òfin tí ó ń de iṣẹ́ ìròyìn yàtọ̀ síra wọn ní orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè èyí ti ó nííṣe pẹ̀lú ànfaní ẹ̀tọ́ ìsọ̀rọ̀ láìsí ìfòyà, ẹ̀tọ́ ìkóròyìn jọ tàbí fífi ìròyìn lède, tí ó fi mọ́ ìbanilórúkọ jẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Dídé internet ati awọn fóònù ti mú ìyàtọ̀ tó pinminrin bá iṣẹ́ ìkóròyìn jọ láti ibẹ̀rẹ̀ ẹgbàá ọdún tí a wà yí (2000). Púpọ̀ àwọn ònkàròyìn ni wọ́n yí padà kúrò níbi kí wọ́ ma ka ìròyìn láti oríÌwé-ìròyìn olójoojúmọ́, Ìwé-ìròyìn àtìgbà-dégbà, tàbí kí wọ́n jókòó sídí ẹ̀rọ rédíò láti gbọ́ ìròyìn tí wọ́n sì ti ń ka àwọn ìròyìn ọlọ́kan-ò-jọkan lórí fóònù wọn. Gbogbo ilé-iṣẹ́ ìròyìn pátá náà ni eọ́ ti gbọ́n já ìlànà ọ̀tun tí internet mú wọ inú iṣẹ́ wọn tí àwọn náà sì tj sọ gbogbo ojú òpó ìròyìn wọn dowó, nítorí wípé tìrẹ Ìwé-ìròyìn jáde kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ mọ́ tí owó tí wọ́n ń pa níbẹ̀ náà ti dínkù jọjọ.[2]