Isaiah Washington
From Wikipedia, the free encyclopedia
Isaiah Washington IV jẹ́ òṣèrékùnrin ti ilẹ̀ American, àti aṣagbátẹrù fíìmù. Lẹ́yìn ìfarahàn rẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù, bíi ṣíṣe ẹ̀dá ìtàn Dr. Preston Burke nínú apá kìíní ti fíìmù Grey's Anatomy láti ọdún 2005 wọ ọdún 2007, ó di gbajúmọ̀ òṣèré.
Quick Facts Ọjọ́ìbí, Ọmọ orílẹ̀-èdè ...
Isaiah Washington | |
---|---|
Washington at the 2013 San Diego Comic-Con | |
Ọjọ́ìbí | Isaiah Washington IV Houston, Texas, U.S.[1] |
Ọmọ orílẹ̀-èdè |
|
Iléẹ̀kọ́ gíga | Howard University |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1991–present |
Close
Washington bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ nípa àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùdarí fíìmù bíi Spike Lee nínú fíìmù Crooklyn (1994), Clockers (1995), Girl 6 (1996), àti Get on the Bus (1996). Ó tún farahàn nínú Love Jones (1997), Bulworth (1998), Out of Sight (1998), True Crime (1999), Romeo Must Die (2000), Exit Wounds (2001), Ghost Ship (2002), àti Hollywood Homicide (2003).
Ní ọdún 2020, Washington di olóòtú ètò kan lórí Fox Nation.[2] Ní ọdún 2022, ó kópa nínú fíìmù Corsicana (2022).