Evangeline Lilly
From Wikipedia, the free encyclopedia
Nicole Evangeline Lilly (tí a bí ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 1979)[1][2] jẹ́ òṣèrébìnrin àti òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀ èdè Kanada. Ó gbajúmọ̀ nígbà tí ó kó ipa Kate Austen nínú eré tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Lost (2004–2010), òun sì ló jẹ́ kí wọ́n yán fún àmì-ẹ̀yẹ Golden Globe Award for Best Actress in a Drama Series.[3]
Quick Facts Ọjọ́ìbí, Iléẹ̀kọ́ gíga ...
Close
Lilly ti kópa nínú ọ̀pọ̀lopọ̀ fíìmù bi The Hurt Locker (2008), Real Steel (2011), gẹ́gẹ́ bi Tauriel nínú àwọn fíìmù The Hobbit, nínú The Desolation of Smaug (2013) àti The Battle of the Five Armies (2014). Ó kó ipa Hope van Dyne nínú fíìmù Marvel Cinematic Universe tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Ant-Man (2015). Lilly tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìwé àwọn ọmọdé tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ The Squickerwonkers.