Aisha Yesufu
Ajafeto omo ènìyàn ni orílè-èdè Nàìjirià / From Wikipedia, the free encyclopedia
Aisha Yusufu (tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejìlá ọdún 1973 ní Ipinle Kano) jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ ọ́ ọmọ ènìyàn, ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti alábàṣiṣẹ́pọ̀ ẹgbẹ́ tí ó ń polongo fún ìdápadà àwọn ọmọ obìnrin wa (Bring Back Our Girls Movement), èyí tí í ṣe ẹgbẹ́ alágbàwí tí ó ń pe Ìjọba sí àkíyèsi lórí í àwọn ọmọbìnrin tí ó lé ní igba láti ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì ti Chibok ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí àwọn ẹgbẹ́ oníjàgídíjàgan Boko Haram jí gbé ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹrin ọdún 2014. Yesufu wà lára àwọn obìnrin tí wọ́n ń fi ẹ̀rónú hàn ní ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí tí ó wà ní Abuja, Olú-ìlú Nàìjíríà, ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹrin, ọdún 2014.[1][2]
Aisha Yesufu | |
---|---|
Aisha Yesufu leading the EndSARS Protest in Abuja, on October 10, 2020. | |
Ọjọ́ìbí | Aisha Yesufu 12 Oṣù Kejìlá 1973 (1973-12-12) (ọmọ ọdún 50) Kano State |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Bayero University Kano |
Iṣẹ́ | Socio-political activist, microbiologist, businesswoman |
Gbajúmọ̀ fún | Bring Back Our Girls, End SARS |
Àwọn ọmọ | 2 |
Yesufu tún wà lára àwọn tí ó léwájú nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń pè fún fífòpin sí SARS (END SARS), èyí tí ó ń pe àkíyèsi si àṣejù tí ẹ̀yà kan nínú iṣé ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ń pè ní Special Anti Robery Squad (SARS) ń ṣe. Yesufu sọ wípé òun kò ní fi ìjà kíkéde ìfòpin sí àwọn ọlọ́pàá SARS ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílẹ̀ fún àwọn ọmọ òun.[3]