Tina Fey
Òṣèré Ọmọ Orílẹ̀-èdè America / From Wikipedia, the free encyclopedia
Elizabeth Stamatina "Tina" Fey ( /feɪ/; tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù karùn-ún ọdún 1970) jẹ́ òṣerébìnrin, aláwàdà ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Fey wà lára àwọn tí ó ko eré NBC sketch comedy tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Saturday Night Live láti ọdún 1997 títí di 2006. Òun ni ó sagbátẹ̀rù sitcom 30 Rock (2006–2013, 2020) àti eréNetflix tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Unbreakable Kimmy Schmidt (2015–2020). Fey tún gbajúmò fún ipa rẹ̀ nínú àwọn eré bi Mean Girls (2004), Baby Mama (2008), Date Night (2010), Megamind (2010), Muppets Most Wanted (2014), Sisters (2015), Whiskey Tango Foxtrot (2016), Wine Country (2019), Soul (2020), àti A Haunting in Venice (2023).
Fey tí gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹyẹ bi àmì ẹyẹ Primetime Emmy mẹ́sàn-án, Golden Globe Awards mẹ́ta, àmì ẹyẹ Screen Actors Guild márùn-ún, àti àmì ẹyẹ Writers Guild of America méje. Ní ọdún 2008, Associated Press fún Fey ní àmì ẹyẹ AP Entertainer fún ọdún náà fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Sarah Palin ní SNL. Ní ọdún 2010, Fey tún gbà àmì ẹyẹ Mark Twain Prize for American Humor.