King Sunny Adé
From Wikipedia, the free encyclopedia
Olóyè Sunday Adéníyì Adégẹyè (ọjọ́ọ̀bí- Ọjọ́ kejìlélógún Oṣù Ọ̀wẹwẹ̀, Ọdún 1946), tí a mọ̀ sí King Sunny Adé, jẹ́ olórin jùjú ọmọ Nàìjíríà, òǹkọ̀tàn-orin àti onimọ̀-ọlọ́pọ̀ irinṣẹ́. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olórin tàkasúfèé tí ó ṣe àṣeyọrí káríayé, tí wọ́n sì tún mọ̀ ọ́ bí ọkàn lára àwọn olórin tó làmìlaka nígbà gbogbo.
King Sunny Adé | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Sunday Adeniyi Adegeye |
Ọjọ́ìbí | 22 Oṣù Kẹ̀sán 1946 (1946-09-22) (ọmọ ọdún 77) Oshogbo, Nigeria |
Irú orin | Jùjú, African pop |
Occupation(s) | Olórin |
Years active | 1960s–present |
Labels | I.R.S. |
Sunny Adé dá ẹgbẹ́ olórin àkọ́kọ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún 1967, tí ó pè ní African Beats. Lẹ́yìn tí ó di onílùúmọ̀ọ́nká ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó dá ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀ sílẹ̀ ni àkókò 1970, Sunny Ade bá ilé-iṣẹ́ Island Records ṣiṣẹ́ ní 1982 tí àwọn àwo rẹ̀ Juju Music (1982) àti Synchro System (1983) sì jẹ́ àgbà wọlé ní káríayé. Synchro System yìí ló mu wọlé gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n du ipò Grammy, tí ó mu jẹ́ olórin àkọ́kọ́ láti Nàìjíríà tí yóò dé irú ipò bẹ́ẹ̀.
Iṣẹ́ àwo rẹ̀ tí ó pè ní Odù náà jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Grammy.
Sunny Ade ni ó jẹ́ alága ẹgbẹ́ olórin ti Nàìjíríà ní àkókò yìí.