Àwọn àkókò tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní fòpin sí owo-eru àti Iwofa
From Wikipedia, the free encyclopedia
Fífòpin sí Ẹrú kíkó wáyé lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni oríṣiríṣi orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹlẹ̀ léraléra ní tẹ́lẹ̀ntẹ́lẹ̀ ní ìpele tí ó ju ọkàn lọ - fún àpẹẹrẹ, fífòpin sí ẹrú kíkó wáyé ní àwọn àgbègbè kan gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ibòmíràn gẹ́gẹ́ àṣẹ ìṣèjọba àgbègbè wọn. Ìgbésẹ̀ òpin yìí máa ń dá lé òfin tàbí ilana tí ìjọba kọ̀ọ̀kan là kalẹ̀ láti fi dè é. Àwọn àkókò wọ̀nyí yóò ṣàfihàn àwọn òfin àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n fòpin sí ẹrú kíkó àti ìwọ̀fà níní ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé.
Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹrú kíkó jẹ́ ìwà ọ̀daràn lóòótọ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé lónìí, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ibi ni okoòwò ẹrú ṣì tún wà káàkiri ní àgbáyé, pàápàá jùlọ nílẹ̀ adúláwọ̀ Áfríkà, Asia, àti Eastern Europe, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ìjọba.[1]